1. BAYI ni gbogbo iṣẹ ti Solomoni ṣe fun ile Oluwa pari: Solomoni si mu gbogbo nkan ti Dafidi baba rẹ̀ ti yà si mimọ́ wá sinu rẹ̀; ati fadakà, ati wura, ati gbogbo ohun-elo, li o fi sinu iṣura ile Ọlọrun.
2. Nigbana ni Solomoni pe awọn àgbagba Israeli jọ, ati gbogbo olori awọn baba awọn ọmọ Israeli si Jerusalemu, lati mu apoti-ẹri majẹmu Oluwa gòke lati ilu Dafidi wá, ti iṣe Sioni.
3. Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pejọ sọdọ ọba li ajọ, eyi ni oṣù keji.