15. Awọn akọrin, awọn ọmọ Asafu duro ni ipò wọn, gẹgẹ bi ofin Dafidi, ati ti Asafu, ati ti Hemani, ati ti Jedutuni, ariran ọba; awọn adèna si duro ni olukuluku ẹnu-ọ̀na; nwọn kò gbọdọ lọ kuro li ọ̀na-iṣẹ wọn, nitoriti awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi, ti mura silẹ dè wọn.
16. Bẹ̃ni a si mura gbogbo ìsin Oluwa li ọjọ kanna, lati pa irekọja mọ́, ati lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ Oluwa, gẹgẹ bi ofin Josiah, ọba.
17. Ati awọn ọmọ Israeli ti a ri nibẹ, pa irekọja na mọ́ li akoko na, ati ajọ aiwukara li ọjọ meje.
18. Kò si si irekọja kan ti o dabi rẹ̀ ti a ṣe ni Israeli lati igba ọjọ Samueli woli; bẹ̃ni gbogbo awọn ọba Israeli kò pa iru irekọja bẹ̃ mọ́, bi eyi ti Josiah ṣe, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Juda ati Israeli ti a ri nibẹ, ati awọn ti ngbe Jerusalemu.
19. Li ọdun kejidilogun ijọba Josiah li a pa irekọja yi mọ́.
20. Lẹhin gbogbo eyi, ti Josiah ti tun ile na ṣe tan, Neko, ọba Egipti, gòke wá, si Karkemiṣi lẹba odò Euferate: Josiah si jade tọ̀ ọ.
21. Ṣugbọn o rán ikọ̀ si i, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, iwọ ọba Juda? Emi kò tọ̀ ọ wá loni, bikòṣe si ile ti mo ba ni ijà: Ọlọrun sa pa aṣẹ fun mi lati yara: kuro lọdọ Ọlọrun, ẹniti o wà pẹlu mi, ki on má ba pa ọ run.
22. Ṣugbọn Josiah kò yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ rẹ̀, ṣugbọn o pa aṣọ ara rẹ dà, ki o le ba a jà, kò si fi eti si ọ̀rọ Neko lati ẹnu Ọlọrun wá, o si wá ijagun li àfonifoji Megiddo.
23. Awọn tafatafa si ta Josiah, ọba: ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ gbé mi kuro; nitoriti mo gbà ọgbẹ gidigidi.
24. Nitorina awọn iranṣẹ rẹ̀ gbé e kuro ninu kẹkẹ́ na, nwọn si fi i sinu kẹkẹ́ rẹ̀ keji; nwọn si mu u wá si Jerusalemu, o si kú, a si sìn i ninu ọkan ninu awọn iboji awọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalemu si ṣọ̀fọ Josiah.