20. Bayi ni Hesekiah si ṣe ni gbogbo Juda, o si ṣe eyiti o dara, ti o si tọ́, ti o si ṣe otitọ, niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
21. Ati ninu gbogbo iṣẹ ti o bẹ̀rẹ ninu iṣẹ-ìsin ile Ọlọrun, ati ninu ofin, ati ni aṣẹ, lati wá Ọlọrun, o fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe e, o si ṣe rere.