2. Kro 30:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. HESEKIAH si ranṣẹ si gbogbo Israeli ati Juda, o si kọ iwe pẹlu si Efraimu ati Manasse, ki nwọn ki o wá sinu ile Oluwa ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa, Ọlọrun Israeli.

2. Nitoriti ọba ti gbìmọ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ijọ-enia ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ li oṣù keji.

3. Nitoriti nwọn kò le pa a mọ́ li akokò na, nitori awọn alufa kò ti iyà ara wọn si mimọ́ to; bẹ̃li awọn enia kò ti ikó ara wọn jọ si Jerusalemu.

4. Ọran na si tọ́ loju ọba ati loju gbogbo ijọ-enia.

2. Kro 30