2. Kro 3:4-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ati iloro ti mbẹ niwaju ile na, gigùn rẹ̀ ri gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgọfa; o si fi kiki wura bò o ninu.

5. O si fi igi-firi bò ile ti o tobi, o si fi wura daradara bò o, o si gbẹ́ àworan igi-ọpẹ ati ẹ̀wọn si i.

6. O si fi okuta iyebiye ṣe ile na li ọṣọ́ fun ẹwà: wura na si jasi wura Parfaimu.

7. O si fi wura bò ile na pẹlu, ati ìti, opó, ati ogiri rẹ̀ wọnni, ati ilẹkun rẹ̀ mejeji; o si gbẹ́ àworan awọn kerubu si ara ogiri na.

8. O si ṣe ile mimọ́-jùlọ na, gigùn eyiti o wà gẹgẹ bi ibu ile na, ogún igbọnwọ: ati ibu rẹ̀, ogún igbọnwọ: o si fi wura daradara bò o, ti o to ẹgbẹta talenti.

9. Oṣuwọn iṣó si jasi ãdọta ṣekeli wura. On si fi wura bò iyara òke wọnni.

10. Ati ninu ile mimọ́-jùlọ na, o ṣe kerubu meji ti iṣẹ ọnà finfin, o si fi wura bò wọn.

11. Iyẹ awọn kerubu na si jẹ ogún igbọnwọ ni gigùn: iyẹ kan jẹ igbọnwọ marun, ti o kan ogiri ile na, iyẹ keji si jẹ igbọnwọ marun, ti o kan iyẹ kerubu keji.

12. Ati iyẹ kerubu keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan ogiri ile na: ati iyẹ keji jẹ igbọnwọ marun ti o kan iyẹ kerubu keji.

13. Iyẹ kerubu wọnyi nà jade ni ogún igbọnwọ: nwọn si duro li ẹsẹ wọn, oju wọn si wà kọju si ile.

14. O si ṣe iboju alaro, ati elése aluko ati òdodó, ati ọ̀gbọ daradara, o si ṣiṣẹ awọn kerubu lara wọn.

15. O si ṣe ọwọ̀n meji igbọnwọ marundilogoji ni giga niwaju ile na, ati ipari ti mbẹ lori ọkọkan wọn si jẹ igbọnwọ marun.

16. O si ṣe ẹ̀wọn ninu ibi-idahùn na, o si fi wọn si ori awọn ọwọ̀n na: o si ṣe awọn pomegranate ọgọrun, o si fi wọn si ara ẹ̀wọn na.

17. O si gbé awọn ọwọ̀n na ro niwaju ile Ọlọrun, ọkan li apa ọtún, ati ekeji li apa òsi, o si pe orukọ eyi ti mbẹ li apa ọtún ni Jakini, ati orukọ eyi ti mbẹ li apa òsi ni Boasi.

2. Kro 3