22. Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ.
23. Nwọn si mu awọn òbukọ ẹbọ-ẹ̀ṣẹ wá siwaju ọba ati ijọ enia na: nwọn si fi ọwọ wọn le wọn lori.
24. Awọn alufa si pa wọn, nwọn si fi ẹ̀jẹ wọn ṣe ilaja lori pẹpẹ, lati ṣe etutu fun gbogbo Israeli; nitoriti ọba paṣẹ, ki a ṣe ẹbọ sisun ati ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli.
25. O si mu awọn ọmọ Lefi duro ninu ile Oluwa, pẹlu kimbali, pẹlu ohun-elo orin, ati pẹlu duru, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi, ati ti Gadi, ariran ọba, ati Natani, woli, nitori aṣẹ Oluwa ni lati ọwọ awọn woli rẹ̀.
26. Awọn ọmọ Lefi si duro pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ati awọn alufa pẹlu ipè.
27. Hesekiah si paṣẹ lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ na. Nigbati ẹbọ sisun na si bẹ̀rẹ, orin Oluwa bẹ̀rẹ pẹlu ipè ati pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ọba Israeli.
28. Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bẹ̃ titi ẹbọ sisun na fi pari tan.