2. Kro 28:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNI ogun ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu: on kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀:

2. Nitoriti o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, o si ṣe ere didà fun Baalimu pẹlu.

2. Kro 28