1. ẸNI ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jotamu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku.
2. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe; kiki kò wọ inu tempili Oluwa lọ, ṣugbọn awọn enia nṣe ibi sibẹsibẹ.
3. On si kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa, ati lori odi Ofeli, o kọ́ pupọ.
4. Ani o kọ́ ilu wọnni li òke Juda, ati ninu igbo, o mọ ile-odi ati ile-iṣọ.
5. O si ba ọba awọn ara Ammoni jà pẹlu, o si bori wọn. Awọn ara Ammoni si fun u li ọgọrun talenti fadakà li ọdun na, ati ẹgbãrun oṣuwọn alikama, ati ẹgbãrun ti barli. Eyi li awọn ara Ammoni san fun u, ati lọdun keji ati lọdun kẹta.