2. Kro 22:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. O si ṣe buburu loju Oluwa bi ile Ahabu: nitori awọn wọnyi li o nṣe igbimọ̀ rẹ̀ lẹhin ikú baba rẹ̀ si iparun rẹ̀.

5. O tẹle imọ̀ran wọn pẹlu; o si ba Jehoramu, ọmọ Ahabu, ọba Israeli, lọ iba Hasaeli, ọba Siria jagun, ni Ramoti-Gileadi: awọn ara Siria si ṣá Jehoramu li ọgbẹ.

6. O si pada lọ iwora ni Jesreeli, nitori ọgbẹ ti a ṣá a ni Rama, nigbati o fi ba Hasaeli, ọba Siria jà. Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, si sọ̀kalẹ lọ iwò Jehoramu, ọmọ Ahabu, ni Jesreeli, nitoriti o ṣaisan.

7. Iparun Ahasiah lati ọwọ Ọlọrun wá ni, nipa wiwá sọdọ Jehoramu: nigbati o si de, o si ba Jehoramu jade tọ̀ Jehu, ọmọ Nimṣi, ẹniti Oluwa fi ororo yàn lati ké ile Ahabu kuro.

8. O si ṣe nigbati Jehu nmu idajọ ṣẹ sori ile Ahabu, o si ri awọn ijoye Juda, ati awọn ọmọ awọn arakunrin Ahasiah, ti nṣe iranṣẹ fun Ahasiah, o si pa wọn.

2. Kro 22