20. Nwọn si dide ni kutukutu owurọ, nwọn si jade lọ si aginju Tekoa: bi nwọn si ti jade lọ, Jehoṣafati duro, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ará Juda, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu. Ẹ gbà Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́, bẹ̃li a o fi ẹsẹ nyin mulẹ; ẹ gbà awọn woli rẹ̀ gbọ́, bẹ̃li ẹnyin o ṣe rere.
21. O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
22. Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn.
23. Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji.
24. Nigbati Juda si de iha ile-iṣọ li aginju, nwọn wò awọn ọ̀pọlọpọ enia, si kiyesi i, okú ti o ṣubu lulẹ ni nwọn, ẹnikan kò sá asalà.
25. Nigbati Jehoṣafati ati awọn enia rẹ̀ de lati kó ikogun wọn, nwọn ri lara wọn ọ̀pọlọpọ ọrọ̀, ati okú, ati ohun-elo iyebiye, nwọn si kójọ fun ara wọn, jù eyiti nwọn le kó lọ: nwọn si kó ikogun wọn jọ ni ijọ mẹta, nitoriti o sa papọ̀ju.