5. Ile ti emi nkọ́ yio si tobi; nitori titobi ni Ọlọrun wa jù gbogbo awọn ọlọrun lọ.
6. Ṣugbọn tani to lati kọ́ ile fun u, nitori ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà a? tali emi ti emi iba kọ́le fun u, bikòṣe kiki ati sun ẹbọ niwaju rẹ̀?
7. Njẹ nisisiyi rán ọkunrin kan si mi ti o gbọ́n lati ṣiṣẹ ni wura, fadakà, ati ni idẹ, ati ni irin, ati ni èse aluko, ati òdodó ati alaró, ti o si le gbọ́ngbọn ati gbẹgi pẹlu awọn ọkunrin ọlọgbọ́n ti o wà lọdọ mi ni Juda ati Jerusalemu, awọn ẹniti Dafidi baba mi ti pese silẹ.
8. Fi ìti-igi kedari, ati firi, ati algumu ranṣẹ si mi pẹlu, lati Lebanoni wá: emi sa mọ̀ pe awọn iranṣẹ rẹ le gbọ́ngbọn ati ké igi ni Lebanoni; si kiyesi i, awọn ọmọ-ọdọ mi yio wà pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ:
9. Ani lati pèse ìti-igi lọpọlọpọ silẹ fun mi: nitori ile na ti emi mura lati kọ́ tobi, o si ya ni lẹnu.
10. Si wò o, emi o fi fun ilo awọn akégi, ti nké ìti-igi, lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ẹgbãwa òṣuwọn alikama fun onjẹ, ati ẹgbãwa òṣuwọn barli ati ẹgbãwa bati ọti-waini, ati ẹgbãwa bati ororo.
11. Nigbana ni Huramu, ọba Tire, kọwe dahùn o si ranṣẹ si Solomoni pe, Nitori ti Oluwa fẹran awọn enia rẹ̀ li o ṣe fi ọ jọba lori wọn.