O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ ri Jehoṣafati, ni nwọn wipe eyi li ọba Israeli, nitorina nwọn yi i ka lati ba a jà: ṣugbọn Jehoṣafati kigbe, Oluwa si ràn a lọwọ: Ọlọrun si yi wọn pada kuro lọdọ rẹ̀.