2. Kro 18:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JEHOṢAFATI si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ, o si ba Ahabu dá ana.

2. Lẹhin ọdun melokan, on sọ̀kalẹ tọ Ahabu lọ si Samaria. Ahabu si pa agutan ati malu fun u li ọ̀pọlọpọ ati fun awọn enia ti o pẹlu rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati ba a gòke lọ si Ramoti-Gileadi.

3. Ahabu ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati ọba Juda pe, Iwọ o ha ba mi lọ si Ramoti-Gileadi bi? On si da a li ohùn wipe, Emi bi iwọ, ati enia mi bi enia rẹ; awa o pẹlu rẹ li ogun na.

4. Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa loni.

5. Nitorina ọba Israeli kó awọn woli jọ, irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki awa ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Gòke lọ; Ọlọrun yio si fi i le ọba lọwọ.

2. Kro 18