2. Kro 17:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JEHOṢAFATI, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀, o si mu ara rẹ̀ le si Israeli.

2. O si fi ogun sinu gbogbo ilu olodi Juda, o si fi ẹgbẹ-ogun si ilẹ Juda ati sinu ilu Efraimu wọnni, ti Asa baba rẹ̀ ti gbà.

3. Oluwa si wà pẹlu Jehoṣafati, nitoriti o rìn ninu ọ̀na iṣaju Dafidi, baba rẹ̀, kò si wá Baalimu:

4. Ṣugbọn o wá Ọlọrun baba rẹ̀, o si rìn ninu ofin rẹ̀, ki iṣe bi iṣe Israeli.

5. Nitorina ni Oluwa fi idi ijọba na mulẹ li ọwọ rẹ̀; gbogbo Juda si ta Jehoṣafati li ọrẹ, on si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ.

6. Ọkàn rẹ̀ si gbé soke li ọ̀na Oluwa: pẹlupẹlu o si mu ibi giga wọnni ati ere-oriṣa kuro ni Juda.

7. Ati li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o ranṣẹ si awọn ijoye rẹ̀, ani si Benhaili ati si Obadiah ati Sekariah, ati si Netaneeli, ati si Mikaiah, lati ma kọ́ni ninu ilu Juda wọnni.

8. Ati pẹlu wọn, o rán awọn ọmọ Lefi, ani Ṣemaiah, ati Netaniah, ati Sebadiah, ati Asaheli, ati Ṣemiramotu, ati Jehonatani, ati Adonijah, ati Tobijah, ati Tob-Adonijah, awọn ọmọ Lefi; ati pẹlu wọn Eliṣama, ati Jehoramu, awọn alufa.

2. Kro 17