2. Kro 14:8-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Asa si ni ogun ti ngbé asà ati ọ̀kọ, ọkẹ mẹdogun lati inu Juda wá, ati lati inu Benjamini wá, ọkẹ mẹrinla ti ngbé apata ati ti nfa ọrun: gbogbo wọnyi si ni akọni ogun.

9. Sera, ara Etiopia, si jade si wọn, pẹlu ãdọta ọkẹ enia, ati ọ̃dunrun kẹkẹ́; nwọn wá si Mareṣa.

10. Asa si jade tọ̀ ọ, nwọn si tẹ ogun li afonifoji Sefata lẹba Mareṣa.

11. Asa si ke pe Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, Oluwa! lọdọ rẹ bakanna ni fun ọ lati ràn alagbara enia lọwọ, tabi ẹniti kò li agbara: ràn wa lọwọ, Oluwa Ọlọrun wa; nitori ti awa gbẹkẹ le ọ, li orukọ rẹ li awa ntọ ọ̀pọlọpọ yi lọ, Oluwa, iwọ li Ọlọrun wa; máṣe jẹ ki enia ki o bori rẹ,

12. Bẹ̃li Oluwa kọlù awọn ara Etiopia niwaju Asa, ati niwaju Juda: awọn ara Etiopia si sa.

13. Ati Asa ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ lepa wọn de Gerari: a si bi awọn ara Etiopia ṣubu ti ẹnikan kò tun wà li ãye; nitori ti a ṣẹ́ wọn niwaju Oluwa ati niwaju ogun rẹ̀; nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ikogun lọ.

14. Nwọn si kọlu gbogbo ilu yikakiri Gerari: nitori ti ẹ̀ru Oluwa bà wọn, nwọn si kó gbogbo ilu na, nitori ikógun pọ̀ rekọja ninu wọn.

15. Nwọn si kọlù awọn agbo-ẹran-ọsin, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ agutan ati ibakasiẹ lọ, nwọn si pada wá si Jerusalemu.

2. Kro 14