2. Kro 13:12-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Si kiyesi i, Ọlọrun tikararẹ̀ si wà pẹlu wa li Olori wa, ati awọn alufa rẹ̀ pẹlu ipè didún ijaiya lati dún si nyin, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ máṣe ba Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin jà; nitori ẹ kì yio ṣe rere.

13. Ṣugbọn Jeroboamu mu ki ogun-ẹ̀hin ki o bù wọn li ẹhin: bẹ̃ni nwọn mbẹ niwaju Juda, ati ogun-ẹhin na si mbẹ lẹhin wọn.

14. Nigbati Juda si bojuwo ẹhin, si kiyesi i, ogun mbẹ niwaju ati lẹhin: nwọn si ke pè Oluwa, awọn alufa si fún ipè.

15. Olukuluku, ọkunrin Juda si hó: o si ṣe, bi awọn ọkunrin Juda si ti hó, ni Ọlọrun kọlu Jeroboamu ati gbogbo Israeli niwaju Abijah ati Juda.

16. Awọn ọmọ Israeli si sa niwaju Juda: Ọlọrun si fi wọn le wọn lọwọ.

17. Abijah ati awọn enia rẹ̀ si pa ninu wọn li ọ̀pọlọpọ: bẹ̃ni ọkẹ mẹdọgbọn ọkunrin ti a yàn ṣubu ni pipa ninu Israeli.

18. Bayi li a rẹ̀ awọn ọmọ Israeli silẹ li akoko na, awọn ọmọ Juda si bori nitori ti nwọn gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.

19. Abijah si lepa Jeroboamu, o si gbà ilu lọwọ rẹ̀, Beteli pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Jeṣana pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Efraimu pẹlu awọn ilu rẹ̀.

2. Kro 13