1. O si ṣe, nigbati Rehoboamu ti fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ ti o si ti mu ara rẹ̀ le, o kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀.
2. O si ṣe ni ọdun karun Rehoboamu ọba, ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, gòke wá si Jerusalemu, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa.
3. Pẹlu ẹgbẹfa kẹkẹ́, ati ọkẹ́ mẹta ẹlẹṣin: awọn enia ti o ba a ti Egipti wá kò niye; awọn ara Libia, awọn ara Sukki, ati awọn ara Etiopia.
4. O si kọ́ awọn ilu olodi ti iṣe ti Juda, o si wá si Jerusalemu.
5. Nigbana ni Ṣemaiah, woli, tọ̀ Rehoboamu wá, ati awọn ijoye Juda, ti o kojọ pọ̀ si Jerusalemu nitori Ṣiṣaki, o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, enyin ti kọ̀ mi silẹ, nitorina li emi si ṣe fi nyin silẹ si ọwọ Ṣiṣaki.