2. Kro 11:2-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ṣugbọn ọ̀rọ Oluwa tọ Ṣemaiah, enia Ọlọrun, wá, wipe,

3. Sọ fun Rehoboamu ọmọ Solomoni, ọba Juda, ati fun gbogbo Israeli ni Juda ati Benjamini, wipe,

4. Bayi li Oluwa wi, ẹnyin kò gbọdọ gòke lọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ki olukuluku pada si ile rẹ̀: nitori ọ̀ran yi lati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbà ọ̀rọ Oluwa gbọ́, nwọn si yipada kuro lati lọ iba Jeroboamu.

5. Rehoboamu si ngbe Jerusalemu, o si kọ́ ilu olodi ni Juda.

6. O kọ́ Betlehemu pẹlu, ati Etamu, ati Tekoa,

2. Kro 11