2. Kro 1:15-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ọba si ṣe ki fadakà ati wura ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti o wà ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.

16. A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti, ati okùn-ọ̀gbọ: awọn oniṣowo ọba ngbà okùn-ọ̀gbọ na ni iye kan.

17. Nwọn si gòke, nwọn si mu kẹkẹ́ kan lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu ẹṣin jade fun gbogbo awọn ọba ara Hitti, ati fun awọn ọba Siria nipa wọn.

2. Kro 1