5. Nitoripe nigbati awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, ṣugbọn a nwahalà wa niha gbogbo; ìja mbẹ lode, ẹ̀ru mbẹ ninu.
6. Ṣugbọn ẹniti ntù awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tù wa ninu nipa didé Titu;
7. Kì si iṣe nipa didé rẹ̀ nikan, ṣugbọn nipa itunu na pẹlu ti ẹ ti tù u ninu, nigbati o rohin fun wa ifẹ gbigbona nyin, ibanujẹ nyin, ati itara nyin fun mi; bẹni mo si tubọ yọ̀.
8. Nitoripe bi mo tilẹ fi iwe mu inu nyin bajẹ, emi kò kãbámọ̀, bi mo tilẹ ti kabamọ rí: nitoriti mo woye pe iwe nì mu nyin banujẹ, bi o tilẹ jẹ pe fun igba diẹ.
9. Emi yọ̀ nisisiyi, kì iṣe nitoriti a mu inu nyin bajẹ, ṣugbọn nitoriti a mu inu nyin bajẹ si ironupiwada: nitoriti a mu inu nyin bajẹ bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, ki ẹnyin ki o maṣe tipasẹ wa pàdanù li ohunkohun.
10. Nitoripe ibanujẹ ẹni ìwa-bi-Ọlọrun a ma ṣiṣẹ ironupiwada si igbala ti kì mu abamọ wá: ṣugbọn ibanujẹ ti aiye a ma ṣiṣẹ ikú.
11. Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, iṣọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti tó, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! Ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ́ ninu ọran na.