1. ṢUGBỌN mo ti pinnu eyi ninu emi tikarami pe, emi kì yio tun fi ibinujẹ tọ̀ nyin wá.
2. Nitoripe bi emi ba mu inu nyin bajẹ, njẹ tali ẹniti o si nmu inu mi dùn, bikoṣe ẹniti mo ti bà ninu jẹ?
3. Emi si kọwe nitori eyi kanna si nyin pe, nigbati mo ba si de, ki emi ki o máṣe ni ibinujẹ lọdọ wọn, nitori awọn ti emi iba mã yọ̀: nitoriti mo ni igbẹkẹle ninu gbogbo nyin, nitori ayọ̀ mi li ayọ̀ fun gbogbo nyin.