20. Olùṣọ na si sọ wipe, On tilẹ de ọdọ wọn, kò si tun padà wá mọ: wiwọ́ kẹkẹ́ na si dàbi wiwọ́ kẹkẹ́ Jehu ọmọ Nimṣi; nitori o nwọ́ bọ̀ kikankikan.
21. Joramu si wipe, Ẹ dì kẹkẹ́. Nwọn si dì kẹkẹ́ rẹ̀. Joramu ọba Israeli ati Ahasiah ọba Juda si jade lọ, olukulùku ninu kẹkẹ́ rẹ̀, nwọn si jade lọ ipade Jehu, nwọn si ba a ni oko Naboti ara Jesreeli.
22. O si ṣe, nigbati Joramu ri Jehu li o wipe, Jehu, Alafia kọ́? On si wipe, Alafia kini, niwọ̀nbi iwà-agbère Jesebeli ìya rẹ ati iṣe ajẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tobẹ̃?
23. Joramu si yi ọwọ rẹ̀ pada, o si sá, o si wi fun Ahasiah pe, Ọtẹ̀ de, Ahasiah.
24. Jehu si fi gbogbo agbara rẹ̀ fà ọrun o si ta Joramu lãrin apa rẹ̀ mejeji, ọfà na si gbà ọkàn rẹ̀ jade, o si dojubolẹ ninu kẹkẹ́ rẹ̀.
25. Nigbana ni Jehu sọ fun Bidkari balogun rẹ̀, pe, Gbe e ki o si sọ ọ si oko Naboti ara Jesreeli: sa ranti bi igbati temi tirẹ jumọ ngùn kẹkẹ́ lẹhin Ahabu baba rẹ̀, Oluwa ti sọ ọ̀rọ-ìmọ yi sori rẹ̀.
26. Nitõtọ li ana emi ti ri ẹ̀jẹ Naboti ati ẹ̀jẹ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, li Oluwa wi; emi o si san a fun ọ ni oko yi, li Oluwa wi. Njẹ nitorina, ẹ mu u, ki ẹ si sọ ọ sinu oko na gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
27. Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ.
28. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e ninu kẹkẹ́ lọ si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni bojì rẹ̀ pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi.