11. On si tẹ̀ oju rẹ̀ mọ ọ gidigidi, titi oju fi tì i; enia Ọlọrun na si sọkun.
12. Hasaeli si wipe, Ẽṣe ti oluwa mi fi nsọkun? On si dahùn pe, Nitoriti mo mọ̀ ibi ti iwọ o ṣe si awọn ọmọ Israeli: awọn odi agbara wọn ni iwọ o fi iná bọ̀, awọn ọdọmọkunrin wọn ni iwọ o fi idà pa, iwọ o si fọ́ ọmọ wẹwẹ́ wọn tútu, iwọ o si là inu awọn aboyun wọn.
13. Hasaeli si wipe, Ṣugbọn kinla? Iranṣẹ rẹ iṣe aja, ti yio fi ṣe nkan nla yi? Eliṣa si dahùn wipe, Oluwa ti fi hàn mi pe, iwọ o jọba lori Siria.