1. LI ọjọ rẹ̀ ni Nebukadnessari ọba Babeli gòke wá, Jehoiakimu si di iranṣẹ rẹ̀ li ọdun mẹta: nigbana li o pada o si ṣọ̀tẹ si i.
2. Oluwa si rán ẹgbẹ́ ogun awọn ara Kaldea si i, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Siria, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ara Moabu, ati ẹgbẹ́ ogun awọn ọmọ Ammoni, o si rán wọn si Juda lati pa a run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ nipa awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn woli.
3. Nitõtọ lati ẹnu Oluwa li eyi ti wá sori Juda, lati mu wọn kuro niwaju rẹ̀, nitori ẹ̀ṣẹ Manasse, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe;