2. A. Ọba 21:14-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Emi o si kọ̀ iyokù awọn ini mi silẹ, emi o si fi wọn le awọn ọ̀ta wọn lọwọ; nwọn o si di ikogun ati ijẹ fun gbogbo awọn ọ̀ta wọn.

15. Nitori nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju mi, ti nwọn si ti mu mi binu, lati ọjọ ti awọn baba wọn ti jade kuro ni Egipti, ani titi di oni yi.

16. Pẹlupẹlu Manasse ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ pupọjù, titi o fi kún Jerusalemu lati ikangun ikini de ekeji; lẹhin ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o mu Juda ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju Oluwa.

17. Ati iyokù iṣe Manasse, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ṣẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

18. Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ninu ọgba-ile rẹ̀, ninu ọgba Ussa: Amoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

19. Ẹni ọdun mejilelogun ni Amoni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun meji ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Mesullemeti, ọmọbinrin Harusi ti Jotba.

2. A. Ọba 21