6. Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Jordani. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Awọn mejeji si jùmọ nlọ.
7. Adọta ọkunrin ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro lati wò lòkere rére: awọn mejeji si duro li ẹba Jordani.
8. Elijah si mu agbáda rẹ̀, o si lọ́ ọ lù, o si lù omi na, o si pin wọn ni iyà sihin ati sọhun, bẹ̃ni awọn mejeji si kọja ni ilẹ gbigbẹ.
9. O si ṣe, nigbati nwọn kọja tan, ni Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ìlọ́po meji ẹmi rẹ ki o bà le mi.
10. On si wipe, Iwọ bère ohun ti o ṣoro: ṣugbọn, bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃ kọ, kì yio ri bẹ̃.
11. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, ti nwọn nsọ̀rọ, si kiyesi i, kẹkẹ́ iná ati ẹṣin iná si là ãrin awọn mejeji; Elijah si ba ãjà gòke re ọrun.