12. Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun; bi Gosani, ati Harani, ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti o wà ni Telassari?
13. Nibo li ọba Hamati, ati ọba Arpadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, ti Hena, ati Ifa gbe wà?
14. Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn onṣẹ na, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ sinu ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa.
15. Hesekiah si gbadura niwaju Oluwa, o si wipe: Oluwa Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikanṣoṣo, ninu gbogbo awọn ilẹ-ọba aiye; iwọ li o dá ọrun on aiye.
16. Dẹti rẹ silẹ Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: ki o si gbọ́ ọ̀rọ Sennakeribu ti o rán lati kẹgàn Ọlọrun alãyè.
17. Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti pa awọn orilẹ-ède run ati ilẹ wọn.