1. O si ṣe li ọdun kẹta Hoṣea ọmọ Ela ọba Israeli ni Hesekiah ọmọ Ahasi ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
2. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n li on nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkandilọgbọ̀n ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Abi ọmọbinrin Sakariah.
3. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.
4. On mu ibi giga wọnni kuro, o si fọ́ awọn ere, o si wó awọn ere oriṣa lulẹ, o si fọ́ ejò idẹ na tútu ti Mose ti ṣe: nitori titi di ọjọ wọnni, awọn ọmọ Israeli nsun turari si i: a si pè e ni Nehuṣtani.