2. A. Ọba 15:10-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ṣallumu ọmọ Jabeṣi si dì rikiṣi si i, o si kọlù u niwaju awọn enia, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.

11. Ati iyokù iṣe Sakariah, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

12. Eyi li ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun Jehu wipe, Awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli, bẹ̃li o si ri.

13. Ṣallumu ọmọ Jabeṣi bẹ̀rẹ si ijọba li ọdun kọkandilogoji Ussiah ọba Juda; o si jọba oṣù kan gbáko ni Samaria.

14. Nitoriti Menahemu ọmọ Gadi gòke lati Tirsa lọ, o si wá si Samaria, o si kọlù Ṣallumi ọmọ Jabeṣi ni Samaria, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.

15. Ati iyokù iṣe Ṣallumu, ati rikiṣi rẹ̀ ti o dì, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

16. Nigbana ni Menahemu kọlù Tifsa, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ agbègbe rẹ̀ wọnni lati Tifsa lọ: nitoriti nwọn kò ṣi i silẹ fun u, nitorina li o ṣe kọlù u; ati gbogbo awọn obinrin aboyun inu rẹ̀ li o là ni inu.

17. Li ọdun kọkandilogoji Asariah ọba Juda ni Menahemu ọmọ Gadi bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba ọdun mẹwa ni Samaria.

18. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, li ọjọ rẹ̀ gbogbo.

19. Fulu ọba Assiria si gbé ogun tì ilẹ na: Menahemu si fi ẹgbẹrin talenti fadakà fun Fulu, ki ọwọ rẹ̀ ki o le pẹlu on lati fi idi ijọba na mulẹ lọwọ rẹ̀.

2. A. Ọba 15