4. Jehoaṣi si wi fun awọn alufa pe, Gbogbo owo ti a yà si mimọ́ ti a si mu wá sinu ile Oluwa, ani olukuluku owo ti o kọja, ati owo idiyele olukuluku, ati gbogbo owo ti o ti inu ọkàn olukuluku wá lati mu wá sinu ile Oluwa.
5. Ẹ jẹ ki awọn alufa ki o mu u tọ̀ ara wọn, olukuluku lati ọwọ ojulùmọ rẹ̀: ẹ si jẹ ki nwọn ki o tun ẹya ile na ṣe, nibikibi ti a ba ri ẹya.
6. O si ṣe, li ọdun kẹtalelogun Jehoaṣi ọba, awọn alufa kò iti tun ẹya ile na ṣe.
7. Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na.
8. Awọn alufa si ṣe ilerí lati má gbà owo lọwọ awọn enia mọ, tabi lati má tun ẹya ile na ṣe.
9. Ṣugbọn Jehoiada alufa mu apoti kan, o si dá ideri rẹ̀ lu, o si fi i si ẹba pẹpẹ na, li apa ọtún bi ẹnikan ti nwọ̀ inu ile Oluwa lọ: awọn alufa ti o si ntọju iloro na fi gbogbo owo ti a mu wá inu ile Oluwa sinu rẹ̀.