15. Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa.
16. Nwọn si gbé ọwọ le e; on si gbà ọ̀na ti awọn ẹṣin ngbà wọ̀ ile ọba: nibẹ ni a si pa a.
17. Jehoiada si da majẹmu lãrin Oluwa ati ọba ati awọn enia, pe, ki nwọn ki o mã ṣe enia Oluwa; ati lãrin ọba pẹlu awọn enia.
18. Gbogbo enia ilẹ na si lọ sinu ile Baali, nwọn si wo o lulẹ: awọn pẹpẹ rẹ̀ ati awọn ere rẹ̀ ni nwọn fọ́ tútu patapata, nwọn si pa Mattani alufa Baali niwaju pẹpẹ na. Alufa na si yàn awọn olori si ile Oluwa.
19. On si mu awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, ati awọn ẹ̀ṣọ, ati gbogbo enia ilẹ na; nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá, nwọn si gbà oju ẹnu-ọ̀na ẹ̀ṣọ wọ̀ ile ọba. O si joko lori ìtẹ awọn ọba.