8. Angẹli keji si fun, a si wọ́ ohun kan bi òke nla ti njona sọ sinu okun: idamẹta okun si di ẹ̀jẹ;
9. Ati idamẹta awọn ẹda ti mbẹ ninu okun ti o ni ẹmí si kú; ati idamẹta awọn ọkọ̀ si bajẹ.
10. Angẹli kẹta si fun, irawọ̀ nla kan ti njo bi fitila si bọ́ lati ọrun wá, o si bọ sori idamẹta awọn odo ṣiṣàn, ati sori awọn orisun omi;
11. A si npè orukọ irawọ na ni Iwọ idamẹta awọn omi si di iwọ, ọ̀pọlọpọ enia si ti ipa awọn omi na kú, nitoriti a sọ wọn di kikorò.
12. Angẹli kẹrin si fun, a si kọlu idamẹta õrùn, ati idamẹta oṣupa, ati idamẹta awọn irawọ, ki idamẹta wọn le ṣõkun, ki ọjọ maṣe mọlẹ fun idamẹta rẹ̀, ati oru bakanna.