Ifi 16:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun.

4. Ẹkẹta si tú ìgo tirẹ̀ sinu odò, ati si orisun awọn omi; nwọn si di ẹ̀jẹ.

5. Mo si gbọ́ angẹli ti omi nì wipe, Olododo ni Iwọ Ẹni-Mimọ́, ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, nitoriti iwọ ṣe idajọ bayi.

6. Nitoriti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́ ati ti awọn woli silẹ, iwọ si fi ẹ̀jẹ fun wọn mu; eyiyi li o yẹ wọn.

7. Mo si gbọ́ pẹpẹ nke wipe, Bẹ̃ni, Oluwa Ọlọrun Olodumare, otitọ ati ododo ni idajọ rẹ.

8. Ẹkẹrin si tú ìgo tirẹ̀ sori õrùn; a si yọnda fun u lati fi iná jó enia lara.

9. A si fi õru nla jo awọn enia lara, nwọn si sọ̀rọ-òdi si orukọ Ọlọrun, ẹniti o li agbara lori iyọnu wọnyi: nwọn kò si ronupiwada lati fi ogo fun u.

10. Ẹkarun si tu ìgo tirẹ̀ sori ìtẹ ẹranko na; ilẹ-ọba rẹ̀ si ṣokunkun; nwọn si nge ahọn wọn jẹ nitori irora.

11. Nwọn si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ọrun nitori irora wọn ati nitori egbò wọn, nwọn kò si ronupiwada iṣẹ wọn.

Ifi 16