13. Mo si ri awọn ẹmí aimọ́ mẹta bi ọ̀pọlọ́, nwọn ti ẹnu dragoni na ati ẹnu ẹranko na ati ẹnu woli eke na jade wá.
14. Nitori ẹmi èṣu ni wọn, ti nṣe iṣẹ-iyanu, awọn ti njade lọ sọdọ awọn ọba gbogbo ilẹ aiye, lati gbá wọn jọ si ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.
15. Kiyesi i, mo mbọ̀ bi olè. Ibukún ni fun ẹniti nṣọna, ti o si npa aṣọ rẹ̀ mọ́, ki o má bã rìn ni ìhoho, nwọn a si ri itiju rẹ̀.
16. O si gbá wọn jọ si ibikan ti a npè ni Har-mageddoni li ède Heberu.