Ifi 15:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si ri àmi miran li ọrun ti o tobi ti o si yanilẹnu, awọn angẹli meje ti o ni awọn iyọnu meje ikẹhin, nitori ninu wọn ni ibinu Ọlọrun de opin.

2. Mo si ri bi ẹnipe òkun digí ti o dàpọ pẹlu iná: awọn ti o si duro lori okun digi yi jẹ awọn ti nwọn ti ṣẹgun ẹranko na, ati aworan rẹ̀, ati ami rẹ̀ ati iye orukọ rẹ̀, nwọn ni dùru Ọlọrun.

3. Nwọn si nkọ orin ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ati orin ti Ọdọ-Agutan, wipe, Titobi ati iyanu ni awọn iṣẹ rẹ, Oluwa Ọlọrun Olodumare; ododo ati otitọ li ọ̀na rẹ, iwọ Ọba awọn orilẹ-ede.

4. Tani kì yio bẹ̀ru, Oluwa, ti kì yio si fi ogo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mimọ́: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio si wá, ti yio si foribalẹ niwaju rẹ; nitori a ti fi idajọ rẹ hàn.

Ifi 15