13. Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá nwi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Alabukún fun li awọn okú ti o kú nipa ti Oluwa lati ìhin lọ: Bẹni, li Ẹmí wi, ki nwọn ki o le simi kuro ninu lãlã wọn, nitori iṣẹ wọn ntọ̀ wọn lẹhin.
14. Mo si wò, si kiyesi i, awọsanma funfun kan, ati lori awọsanma na ẹnikan joko ti o dabi Ọmọ-enia, ti on ti ade wura li ori rẹ̀, ati dòjé mimú li ọwọ́ rẹ̀.
15. Angẹli miran si ti inu tẹmpili jade wá ti nke li ohùn rara si ẹniti o joko lori awọsanma pe, Tẹ̀ doje rẹ bọ̀ ọ, ki o si mã kore: nitori akokò ati kore de, nitori ikorè aiye ti gbó tan.
16. Ẹniti o joko lori awọsanma na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ori ilẹ aiye; a si ṣe ikore ilẹ aiye.
17. Angẹli miran si ti inu tẹmpili ti mbẹ li ọrun jade wá, ti on ti doje mimu.