7. A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ.
8. Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.
9. Bi ẹnikẹni ba li etí ki o gbọ́.
10. Bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a di ẹni igbèkun, igbèkun ni yio lọ: bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a fi idà pa ẹni, idà li a o si fi pa on na. Nihin ni sũru ati igbagbọ́ awọn enia mimọ́ gbé wà.
11. Mo si ri ẹranko miran goke lati inu ilẹ wá; o si ni iwo meji bi ọdọ-agutan, o si nsọ̀rọ bi dragoni.