4. Nwọn si foribalẹ fun dragoni na nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, Tali o dabi ẹranko yi? tali o si le ba a jagun?
5. A si fun u li ẹnu lati mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu mejilelogoji.
6. O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun.