Ifi 12:15-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ejò na si tú omi jade lati ẹnu rẹ̀ wá bi odo nla sẹhin obinrin na, ki o le mu ki ìṣan omi na gbá a lọ.

16. Ilẹ si ràn obinrin na lọwọ, ilẹ si yà ẹnu rẹ̀, o si fi ìṣan omi na mu, ti dragoni na tú jade lati ẹnu rẹ̀ wá.

17. Dragoni na si binu gidigidi si obinrin na, o si lọ ba awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyokù jagun, ti nwọn npa ofin Ọlọrun mọ́, ti nwọn si di ẹrí Jesu mu.

Ifi 12