18. Inu si bi awọn orilẹ-ède, ibinu rẹ si de, ati ìgba lati dá awọn okú lẹjọ, ati lati fi ere fun awọn iranṣẹ rẹ woli ati awọn enia mimọ́ ati awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ, ati ẹni kekere ati ẹni nla; ati lati run awọn ti npa aiye run.
19. A si ṣí tẹmpili Ọlọrun silẹ li ọrun, a si ri apoti majẹmu ninu tẹmpili rẹ̀: mànamána si kọ, a si gbọ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀, yinyín nla si bọ.