9. Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi.
10. Mo wà ninu Ẹmí li ọjọ Oluwa, mo si gbọ́ ohùn nla kan lẹhin mi, bi iró ipè,
11. O nwipe, Emi ni Alfa ati Omega, ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: ohun ti iwọ ba si ri, kọ ọ sinu iwe, ki o si rán a si awọn ijọ meje; si Efesu, ati si Smirna, ati si Pergamu, ati si Tiatira, ati si Sardi, ati si Filadelfia, ati si Laodikea.
12. Mo si yipada lati wò ohùn ti mba mi sọ̀rọ. Nigbati mo yipada, mo ri ọpá fitila wura meje;
13. Ati lãrin awọn ọpá fitila na, ẹnikan ti o dabi Ọmọ enia, ti a wọ̀ li aṣọ ti o kanlẹ̀ de ẹsẹ, ti a si fi àmure wura dì li ẹgbẹ.
14. Ori rẹ̀ ati irun rẹ̀ funfun bi ẹ̀gbọn owu, o funfun bi sno; oju rẹ̀ si dabi ọwọ́ iná;
15. Ẹsẹ rẹ̀ si dabi idẹ daradara, bi ẹnipe a dà a ninu ileru; ohùn rẹ̀ si dabi iró omi pupọ̀.