Iṣe Apo 8:27-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Nigbati o si dide, o lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan ara Etiopia, iwẹfa ọlọlá pipọ lọdọ Kandake ọbabirin awọn ara Etiopia, ẹniti iṣe olori gbogbo iṣura rẹ̀, ti o si ti wá si Jerusalemu lati jọsin,

28. On si npada lọ, o si joko ninu kẹkẹ́ rẹ̀, o nkà iwe woli Isaiah.

29. Ẹmí si wi fun Filippi pe, Lọ ki o si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹkẹ́ yi.

30. Filippi si sure lọ, o gbọ́, o nkà iwe woli Isaiah, o si bi i pe, Ohun ti iwọ nkà nì, o yé ọ?

31. O si dahùn wipe, Yio ha ṣe yé mi, bikoṣepe ẹnikan tọ́ mi si ọna? O si bẹ̀ Filippi ki o gòke wá, ki o si ba on joko.

32. Ibi iwe-mimọ́ ti o si nkà na li eyi, A fà a bi agutan lọ fun pipa; ati bi ọdọ-agutan iti iyadi niwaju olurẹrun rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀:

33. Ni irẹsilẹ rẹ̀ a mu idajọ kuro: tani yio sọ̀rọ iran rẹ̀? nitori a gbà ẹmí rẹ̀ kuro li aiye.

34. Iwẹfa si da Filippi lohùn, o ni, Mo bẹ̀ ọ, ti tani woli na sọ ọ̀rọ yi? ti ara rẹ̀, tabi ti ẹlomiran?

Iṣe Apo 8