43. Ẹnyin si tẹwọgbà agọ́ Moloku, ati irawọ oriṣa Remfani, aworan ti ẹnyin ṣe lati mã bọ wọn: emi ó si kó nyin lọ rekọja Babiloni.
44. Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri;
45. Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi;
46. Ẹniti o ri ojurere niwaju Ọlọrun, ti o si tọrọ lati ri ibugbe fun Ọlọrun Jakọbu.
47. Ṣugbọn Solomoni kọ́ ile fun u.
48. Ṣugbọn Ọgá-ogo kì igbé ile ti a fi ọwọ kọ́; gẹgẹ bi woli ti wipe,
49. Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si li apoti itisẹ mi: irú ile kili ẹnyin o kọ́ fun mi? li Oluwa wi; tabi ibo ni ibi isimi mi?
50. Ọwọ́ mi kọ́ ha ṣe gbogbo nkan wọnyi?
51. Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on etí, nigba-gbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmí Mimọ́: gẹgẹ bi awọn baba nyin, bẹ̃li ẹnyin.
52. Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa:
53. Ẹnyin ti o gbà ofin, gẹgẹ bi ilana awọn angẹli, ti ẹ kò si pa a mọ́.
54. Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke.