38. Iwọ ha kọ́ ni ara Egipti nì, ti o ṣọ̀tẹ ṣaju ọjọ wọnyi, ti o si ti mu ẹgbaji ọkunrin ninu awọn ti iṣe apania lẹhin lọ si iju?
39. Ṣugbọn Paulu si wipe, Ju li emi iṣe, ara Tarsu ilu Kilikia, ọlọ̀tọ ilu ti kì iṣe ilu lasan kan, emi si bẹ ọ, bùn mi lãye lati ba awọn enia sọrọ.
40. Nigbati o si ti bùn u lãye, Paulu duro lori atẹgùn, o si juwọ́ si awọn enia. Nigbati nwọn si dakẹrọrọ o ba wọn sọrọ li ède Heberu, wipe,