Iṣe Apo 20:7-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ati ni ọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọ̀rọ rẹ̀ gùn titi di arin ọganjọ.

8. Fitilà pipọ si wà ni yàrá oke na, nibiti a gbé pejọ si.

9. Ọdọmọkunrin kan ti a npè ni Eutiku si joko li oju ferese, orun si wọ̀ ọ lara: bi Paulu si ti pẹ ni iwasu, o ta gbọ́ngbọ́n loju orun, o ṣubu lati oke kẹta wá silẹ, a si gbé e dide li okú.

10. Nigbati Paulu si sọkalẹ, o wolẹ bò o, o gbá a mọra, o ni, Ẹ má yọ ara nyin lẹnu; nitori ẹmí rẹ̀ mbẹ ninu rẹ̀.

11. Nigbati o si tún gòke lọ, ti o si bù akara, ti o si jẹ, ti o si sọ̀rọ pẹ titi o fi di afẹmọjumọ́, bẹ̃li o lọ.

12. Nwọn si mu ọmọkunrin na bọ̀ lãye, inu nwọn si dun gidigidi.

13. Nigbati awa si ṣaju, awa si ṣikọ̀ lọ si Asso, nibẹ̀ li a nfẹ gbà Paulu si ọkọ̀: nitori bẹ̃li o ti pinnu rẹ̀, on tikararẹ̀ nfẹ ba ti ẹsẹ lọ.

14. Nigbati o pade wa ni Asso, ti a si ti gbà a si ọkọ̀, a lọ si Mitilene.

15. Nigbati a si ṣikọ̀ nibẹ̀, ni ijọ keji a de ọkankan Kio; ni ijọ keji rẹ̀ a de Samo, a si duro ni Trogillioni; ni ijọ keji rẹ̀ a si de Miletu.

16. Paulu sá ti pinnu rẹ̀ lati mu ọkọ̀ lọ niha Efesu, nitori ki o ma ba fi igba na joko ni Asia: nitori o nyára bi yio ṣe iṣe fun u, lati wà ni Jerusalemu li ọjọ Pentikosti.

17. Ati lati Miletu o ranṣẹ si Efesu, lati pè awọn alàgba ijọ wá sọdọ rẹ̀.

18. Nigbati nwọn si de ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin tikaranyin mọ̀, lati ọjọ ikini ti mo ti de Asia, bi emi ti ba nyin gbé, ni gbogbo akoko na,

19. Bi mo ti nfi ìrẹlẹ ọkàn gbogbo sìn Oluwa, ati omije pipọ, pẹlu idanwò, ti o bá mi, nipa ìdena awọn Ju:

Iṣe Apo 20