31. Awọn olori kan ara Asia, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ranṣẹ si i, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe fi ara rẹ̀ wewu ninu ile ibiṣire.
32. Njẹ awọn kan nwi ohun kan, awọn miran nwi omiran: nitori ajọ di rudurudu; ati ọ̀pọ enia ni kò mọ̀ itori ohun ti nwọn tilẹ fi wọjọ pọ̀ si.
33. Nwọn si fà Aleksanderu kuro li awujọ, awọn Ju tì i ṣaju. Aleksanderu si juwọ́ si wọn, on iba si wi ti ẹnu rẹ̀ fun awọn enia.
34. Ṣugbọn nigbati nwọn mọ̀ pe Ju ni, gbogbo wọn li ohùn kan, niwọn wakati meji ọjọ, kigbe pe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu.