25. O yẹ loju awa, bi awa ti fi imọ ṣọkan lati yàn enia ati lati rán wọn si nyin, pẹlu Barnaba on Paulu awọn olufẹ wa.
26. Awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi.
27. Nitorina awa rán Juda on Sila, awọn ti yio si fi ọ̀rọ ẹnu sọ ohun kanna fun nyin.
28. Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ:
29. Ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu ẹ̀jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere: ninu ohun ti, bi ẹnyin ba pa ara nyin mọ́ kuro, ẹnyin ó ṣe rere. Alafia.
30. Njẹ nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn sọkalẹ wá si Antioku: nigbati nwọn si pè apejọ, nwọn fi iwe na fun wọn.
31. Nigbati nwọn si kà a, nwọn yọ̀ fun itunu na.
32. Bi Juda on Sila tikarawọn ti jẹ woli pẹlu, nwọn fi ọ̀rọ pipọ gbà awọn arakunrin niyanju, nwọn si mu wọn li ọkàn le.