Iṣe Apo 15:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọkunrin kan ti Judea sọkalẹ wá, nwọn si kọ́ awọn arakunrin pe, Bikoṣepe a ba kọ nyin ni ilà bi iṣe Mose, ẹnyin kì yio le là.

2. Nigbati iyapa ati iyàn jijà ti mbẹ lãrin Paulu on Barnaba kò si mọ ni ìwọn, awọn arakunrin yàn Paulu on Barnaba, ati awọn miran ninu wọn, ki nwọn goke lọ si Jerusalemu, sọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagba nitori ọ̀ran yi.

3. Nitorina nigbati ijọ si sìn wọn de ọna, nwọn là Fenike on Samaria kọja, nwọn nròhin iyipada awọn Keferi: nwọn si fi ayọ̀ nla fun gbogbo awọn arakunrin.

Iṣe Apo 15