Iṣe Apo 13:38-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

38. Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin:

39. Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose.

40. Nitorina ẹ kiyesara, ki eyi ti a ti sọ ninu iwe awọn woli ki o maṣe de ba nyin, pe;

41. Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin.

42. Bi nwọn si ti njade, nwọn bẹ̀bẹ pe ki a sọ̀rọ wọnyi fun wọn li ọjọ isimi ti mbọ̀.

43. Nigbati nwọn si jade ni sinagogu, ọ̀pọ ninu awọn Ju ati ninu awọn olufọkansìn alawọṣe tẹle Paulu on Barnaba: awọn ẹniti o ba wọn sọ̀rọ ti nwọn si rọ̀ wọn lati duro ninu ore-ọfẹ Ọlọrun.

Iṣe Apo 13