Iṣe Apo 12:21-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Lọjọ afiyesi kan, Herodu gunwà, o joko lori itẹ́, o si nsọ̀rọ fun wọn.

22. Awọn enia si hó, wipe, Ohùn ọlọrun ni, kì si iṣe ti enia.

23. Lojukanna angẹli Oluwa lù u, nitoriti kò fi ogo fun Ọlọrun: idin si jẹ ẹ, o si kú.

24. Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun gbilẹ, o si bi si i.

Iṣe Apo 12